We’ve updated our Terms of Use to reflect our new entity name and address. You can review the changes here.
We’ve updated our Terms of Use. You can review the changes here.

Orin Adura, Volume 3

by Tolu Akande

supported by
/
1.
Aye Sin Mbe 04:49
Aye si mbe nile Od'agutan Ewa ogo Re n pe o pe ma bo Wole, wole, wole nisisiyi Ewa ogo Re n pe o pe ma bo Ojo lo tan, orun si fere wo Okunkun de tan, 'mole nkoja lo Wole, wole, wole nisisiyi Okunkun de tan, 'mole nkoja lo Aye si mbe ilekun si sile Ilekun ife, iwo ko pe ju Wole, wole, wole nisisiyi Ilekun ife, iwo ko pe ju K'ile to su, ilekun na le ti 'gba na o k'abamo, "o se! o se!" O se, o se, ko s'aye mo o se 'gba na o k'abamo, "o se! o se!" Eyin ara ati ojulumo E wa wole ki le ayo to kun Gbogbo aiye ni Jesu npe tantan Wa wo oko igbala yi ki o to kun. Yara wa, wa wole Jesu lo npe nyin tantan Yara wa, wa wole Jesu lo npe nyin tantan Yara wa, wa wole Jesu lo npe nyin tantan Ki oko Noah ikehin yi ko to kun tan. Gbogbo Egbe at'Ijo Olorun Keferi ati Imale ilu Gbogbo aiye ni Jesu npe tantan Wa wo oko igbala yi ki o to kun. Yara wa, wa wole Jesu lo npe nyin tantan Yara wa, wa wole Jesu lo npe nyin tantan Yara wa, wa wole Jesu lo npe nyin tantan Ki oko Noah ikehin yi ko to kun tan. Kerubu ati Serafu lo npe nyin Eni Mimo, Israeli lo npe nyin Gbogbo Ogun Orun lo ni k'e wa Wa wo oko igbala yi ki o to kun. Yara wa, wa wole Jesu lo npe nyin tantan Yara wa, wa wole Jesu lo npe nyin tantan Yara wa, wa wole Jesu lo npe nyin tantan Ki oko Noah ikehin yi ko to kun tan. Come who are thirsty! Come who have need!
2.
Lo kede ayo na fun gbogbo aiye, P'Omo Olorun segun iku, Fi tiyin-tiyin pel'ayo rohin na, Emi Mimo to gunwa. Oba mi de, Asegun mi de, Ogo, Ola, at'agbara at'ipa F'Odaguntan to gunwa. Iyin Jesu l'awon Angeli nke, T'o wa ra araiye pada, Okan soso ajanaku ni Jesu, T'o m'aiye pelu orun O de! Oba mi de, Asegun mi de, Ogo, Ola, at'agbara at'ipa F'Odaguntan to gunwa. Bi orile-ede enia dudu, Ati ka wa si eweko, Sugbon awa ni Baba kan l'oke, T'o mo pe 'se Re ni wa! O de! Oba mi de, Asegun mi de, Ogo, Ola, at'agbara at'ipa F'Odaguntan to gunwa. Ojo nla kan ma mbo T'Olusiro y'o de, Gbogbo eniyan y'o ri Aye yio wariri. Igbagbo re ha da Wo ti ko m'Olorun T'o f'eda se igbekele T'o f' Oluwa sile. Ayo pupo yio wa, L'okan ti Jesu ngbe Ti nwon ti ko aiye sile T'o gba Emi Mimo.
3.
Ki se l'ainireti Ni mo to wa; Ki se l'aini 'gbagbo Ni mo kunle: Ese ti gori mi, Eyi sa l' ebe mi, Eyi sa l'ebe mi, Jesu ti ku. A ! ese mi poju, O pon koko ! Adale, adale, Ni mo nd' ese ! Ese aiferan Re; Ese aigba O gbo; Ese aigba O gbo; Ese nlanla ! Oluwa mo jewo Ese nla mi; O mo bi mo ti ri, Bi mo ti wa; Jo we ese mi nu ! K' okan mi mo loni, K' okan mi mo loni, Ki ndi mimo. Olododo ni O O ndariji; L'ese agbelebu Ni mo wole; Je k' eje iwenu, Eje Odagutan, Eje Odagutan, We okan mi. 'Gbana, Alafia Y'o d' okan mi; 'Gbana, ngo ba O rin, Ore airi; Em' o f' ara ti O, Jo ma to mi s' ona, Jo ma to mi s' ona, Titi aiye.
4.
GBANGBA l'oju Re Olorun S'ohun gbogbo ta nse, T'osan t'oru bakanna ni, L'oju Oluwa wa. Ko s'ese kan ti a le da Ko s'oro t'a le so Ti ko si ninu iwe Re Fun iranti gbogbo. Ese ole, ese iro Ese aiforiji Ese ka s'oro eni lehin Baba dariji wa Baba dariji wa. A! l'ojo nla ojo 'dajo [Oluwa!] Ma je k'oju tiwa T'oju gbogbo aiye yio pe Baba dariji wa. Dariji mi Olorun mi, Kin to lo laiye yi, Ko pa gbogbo ese mi re Baba dariji mi. Baba dariji mi. Baba dariji mi.
5.
Isun Kan Wa 04:29
ISUN kan wa to kun f'eje O yo niha Jesu Elese mokun ninu re O bo ninu ebi O bo ninu ebi O bo ninu ebi Elese mokun ninu re O bo ninu ebi. 'Gba mo f'igbagbo r'isun na Ti nsan fun ogbe Re Irapada d'orin fun mi Ti ngo ma ko titi Ti ngo ma ko titi Ti ngo ma ko titi Irapada d'orin fun mi Ti ngo ma ko titi. Duru t'a tow'Olorun se, Ti ko ni baje lai T'a o ma fi iyin Baba wa Oruko Re nikan Oruko Re nikan Oruko Re nikan T'a o ma fi iyin Baba wa Oruko Re nikan Oruko Re nikan [soso] Oruko Re nikan [Baba mi!] Oruko Re nikan.
6.
OLUWA Agbara fohun Bi ara l'oke Sinai Awon Angeli gbohun Re, Nwon si gbon fun iberu. Ipe ndun, Angeli ho Halleluya! l'orin won O n pada bo ninu ogo Lati wa gba ijoba. Jesu Oluwa mbo wa, E jade lo pade Re Opo yio kun fun ayo Opo fun ibanuje. [Oro ipe dun!] Ipe ndun, Angeli ho Halleluya! l'orin won O n pada bo ninu ogo Lati wa gba ijoba. Mase gbekele aiye Ore aiye a fo lo Enit'o gb'aiye m'aiya Y'o gun s'ebute ofo. [Oro ipe dun!] Ipe ndun, [Ipe ayo!] Angeli ho [Angeli ho!] Halleluya! l'orin won [Orin won lo je] O n pada bo ninu ogo [Ninu ola!] Lati wa gba ijoba. Ipe ndun, [Ipe ayo!] Angeli ho [Angeli ho!] Halleluya! l'orin won [Orin won lo je] O n pada bo ninu ogo [Ninu ola!] Lati wa gba ijoba. Ipe ndun, [Ipe ayo!] Angeli ho [Angeli ho] Halleluya! l'orin won [Orin won lo je] O n pada bo ninu ogo [Ninu ola!] Lati wa gba ijoba.
7.
OKAN mi yo ninu Oluwa Tori o je iye fun mi [Tori o je iye fun mi] Ohun re dun pupo lati gbo Adun ni lati r'oju Re Emi yo ninu Re Emi yo ninu Re Gbagbogbo l'o nfi ayo kun nu okan mi Tori emi yo ninu Re. O ti wa mi pe ki nto mo O Gbati mo rin jina sagbo [Gbati mo rin jina sagbo] O gbe mi wa sile l'apa Re Nibiti papa tutu wa [Emi yo] Emi yo ninu Re Emi yo ninu Re Gbagbogbo l'o nfi ayo kun okan mi Tori emi yo ninu Re. Ore at'anu Re yi mi ka Or'ofe Re nsan bi odo [Or'ofe Re nsan bi odo] Emi Re nto, o si nse tunu O ba mi lo sibikibi [Emi yo] Emi yo ninu Re Emi yo ninu Re Gbagbogbo l'o nfi ayo kun okan mi Tori emi yo ninu Re. Emi y'o dabi Re n'ijo kan [O Lord one day] O s'eru wuwo mi kale [O s'eru wuwo mi kale] Titi gbana ngo j'olotito [Hallelujah] K'emi si s'oso pade Re Emi yo ninu Re Emi yo ninu Re Gbagbogbo l'o nfi ayo kun okan mi Tori emi yo ninu Re.
8.
Sure fun wa loni, Baba wa orun A gboju wa soke si O, 'Wo to sure f'Abraham Baba wa, Jowo sure fun wa. Alpha ati Omega A si okan wa paya s'Olodumare Ma je ka lo l'ofo. Metalokan Mimo Alagbara Ife to jinle julo Awamaridi Olodumare Jo f'ire kari wa. Alpha ati Omega A si okan wa paya s'Olodumare Ma je ka lo l'ofo. Awa nke pe O loni, Baba wa, Ma je k'omo Re rahun Ko sohun ti jamo lehin ekun Jowo dabobo wa. Alpha ati Omega A si okan wa paya s'Olodumare Ma je ka lo l'ofo. Wo lo m'omi lat'inu apata F'awon enia Re saju O rojo manna pelu lat'orun Jowo pese fun wa. Alpha ati Omega [Omega] A si okan wa paya s'Olodumare Jowo pese Jo f'ire kari Jowo dabobo Ma je ka lo l'ofo.

credits

released December 28, 2022

license

all rights reserved

tags

about

Tolu Akande Atlanta, Georgia

BOOKING:
470-326-0916

toluakandemusic@gmail.com

Christ-follower. Proudly Nigerian.

"Let me write the songs of a nation, I care not who writes its laws."

The reason why I do hymns? Because the 7 year-old and the 70 year-old alike will sing them. Additionally, they are sound doctrine and theology placed to anointed melodies that have stood the test of time!
... more

contact / help

Contact Tolu Akande

Streaming and
Download help

Shipping and returns

Redeem code

Report this album or account

If you like Tolu Akande, you may also like: